John 2:18-22

18 aNígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Ààmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

19 bJesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

20Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?” 21 cṢùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀. 22 dNítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.

Copyright information for YorBMYO